Rowland Abiodun Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art

Cambridge University Press, New York, 2014, 386p. Four essays presented
at a Roundtable on the book during 2016 African Studies Association
(ASA) conference.

Ẹlẹ́nu Rírì ati Àmù Ìyá Rẹ̀.1

Mọyọ̀ṣọ́rẹ Òkédìjí
University of Texas, Austin
moyo.okediji@utexas.edu

Ar̀ òko ̣ yi ̀i ́ sẹ aỳ eẁ ̣ ò i ̀di ́ abájo ̣ ti ́ ọ̀ro,̀ ̣ er̀ ò at̀ i ́ i s̀ ẹ Ẹ̀èbó fi mú oṃ ú laý à aẁ oṇ oluẁ ádi ̌ at̀ i ọ̀moẁ ̣ e ́ iṣẹ-́ ọnà aláwọ ̀ dúdu ́ ju as̀ ạ ̀ adúlaẃ ọ̀ lo,̣ niẃ ọ̀n ig̀ ba ̀ ti ́ eḷé ̣nu riŕ i ̀ ló ni aà m̀ ù i ỳ á rẹ̀.2 Kaỳ eé fí ̀ yi ̀i ́ ni ó sẹ Ọ̀ jọ̀gbó ̣n ag̀ bà Rowland Abió ́ ̣ duń ti ́ wó ̣n fi oju ́ suǹ nùkuǹ wo ọ̀rọ̀ suǹ nùkuǹ lat́ i ko ̣ iẁ e ́ i ̀jiŕ or̀ o ̀ niṕ a àkójo,̣ àkoś o ̣ at̀ i iruẃ á èdè li ́lò niń ú iṣẹ-́ ọnà aẁ oṇ adúlaẃ o,̀ ̣ paà ṕ aà ́ jùlo ̣ iṣẹ-́ ọnà aẁ oṇ Kaá à ŕ o-̀ ̣ o-o-̀ ji ́ire. Kóko ́ or̀ ̣ ọ̀ ti ́ o ́ jeỵ o ̣ niń u ́ iẁ e ́ Bàba ́ Abió ́ ̣ duń , lé ̣ hiǹ iẁ ádi ̌ ti ́ wó ̣n sẹ fuń ǹkan aà ́dó ̣ta oḍ uń , ni wi ́ pe ́ o ́ sẹ pat̀ àki ̀ lat́ i niŕ an aẁ oṇ i ̀jiǹ lẹ̀ ọ̀rọ̀ ti ́ o ́ jẹ́ iyèkan at̀ i oṃ o ̣ i ỳ a ́ isẹ ́ oṇ a ̀ aẁ oṇ Yorùba ́ niǵ bat̀ i ́ a ba ́ n ́ peri ́ aẁ on isẹ ́ oṇ a ̀ is̀ ẹ̀ǹbaý e ́ woǹ ̣ yi.́ Ar̀ òko ̣ sékéle ́ yi ̀i ́ jiŕ or̀ o ̀ wí pé ́ akólòlo ̀ i r̀ an Yorùbá ti ń pe baba lat́ i oj̣ ó ̣ alaý é ti daý e.́ Ig̀ bà wo ni, at̀ i eè ś e ti ́ woṇ wa ́ bẹ̀rẹ̀ as̀ ạ ̀kasạ ̀ lat́ i maá fi oẉ ó ̣ os̀ i ̀ juẃ e iṣẹ-́ ọnà ilẹ̀ Kaá à ŕ o-̀ ̣ o-o-̀ ji ́ire? Ǹjé ̣ o ́ dájú wi ́ pé aẁ oṇ Yorùbá ni ́ as̀ ạ ̀lò eẉ à èdè tó sẹ̀ lé ̣ńké ̣ jọ̀ fuń aỳ eẁ ̣ ò iṣẹ-́ ọnà wọǹ yí ni ́ ẹ̀kuń ré ̣ré ̣? Bi ́ ó bá jé ̣ beé ̣̣̀, emi ni aẁ oṇ ojúloẃ ó eẉ à èdè woṇ yi ?́ Baẃ o ni a sẹ lè mú woṇ lo?̀ Ǹjé ̣ a tilẹ̀ lè ko ̣ igilango ̣ Yorùbá si ́lẹ̀ ni ́ ọ̀nà ti ́ ó kuń ojú iẁ ọ̀n, ni ́ ẹ̀ kuń ré ̣ré ̣ at̀ i ni ́ ohuǹ ti ́ ó fa og̣ boń ̣ yo ̣ fuń ag̀ beý ẹ̀wò aẁ oṇ isẹ ́ ̣ oṇ a ̀ ti ́ o ́ gbaḿ uś ẹ ́ wọ̀nyi ?́ Ki ́ ni er̀ o ̀ aẁ oṇ ag̀ ba ̀ oniś ẹ ̣ oṇ a ̀ bi ́i Bàba ́ Lam̀ i ́di ̀ Fákéỵ e ̣ niṕ a àbá ki ́ á maá fi as̀ ạ at̀ i er̀ ò Eè ̀bó sẹ àkaẁ é at̀ i àlaỳ é iṣẹ-́ ọnà aẁ oṇ Yorùba?́ Ǹjé ̣ ó bà ni àbi ́ ó ti bàjé ̣ tań porongodo, ti ́ asọ ̣̀ ò si ̀ le ̀ ba ́ Oṃ ó ̣ye ̣ mo?́ ̣ Iẁ oǹ ̣ yi ̌ ni iẁ ọ̀nba kóko ́ dié ̣̀ niń u ́ i ̀fomi-jomi-tooro-ọ̀rọ̀ ti ́ ó jeỵ o ̣ niń ú ar̀ òko ̣ yi ̀i ́ niṕ a pabambari ̀ ọ̀rọ̀ ti ́ Baba Abió ́ ̣ duń sọ̀ kalẹ̀ niń ú iẁ é tuntun yi ̀i.́

Iẁ e ́ ti ́ Ọ̀jọg̀ bọń Rowland Abió ḍ uń ko ̣ ni a ̀ ba ́ pe ̀ ni ́ Eḷé ̣nu Riŕ i ̀ lo ́ Laà m̀ u ̀ Iỳ á a Rẹ̀.3 Kaỳ eé fí ̀ ni ó jé ̣ wí pé´ èdè gẹ̀eś ̣ i,̀ faransé ati potoki ́ feé ̣ ́ ̣ dó ̣gbó ̣n fi èdè woṇ gba iṣẹ-́ ọnà aẁ a alaẃ ọ̀ dúdú ló ̣wó ̣ wa. Bi ́ kò bá si ̀ ni ́ i ̀di,́ obiǹ – rin ki ̀ i ́ jé ̣ Kuḿ ólu.́ Ohun tó sẹ ilá ti ́lá fi ko,́ où n ló sẹ ikaǹ tó fi wẹ̀wù ẹ̀ je.̀ ̣ Ohun tó dé ti ́ ó fi jé ̣ wi ́ pé èdè Gẹ̀é ̣si ̀ at̀ i èdè aẁ oṇ alaẃ ò ̣ funfun ni a fí ń tuḿ ọ̀ iṣẹ-́ ọnà aẁ a Kaá à ŕ ó ̣-o-o-̀ ji ́ire, at̀ i iṣẹ-́ ọnà aẁ oṇ eè ỳ aǹ dúdú yòókù ni ́ ilẹ̀̀ Afí ŕ i ́kà ni ́ i ̀di.́ Dié ̣̀ niń ú aẁ oṇ i ̀di ́ wọ̀nyi ̀i ́ ni mo fé ̣ mé ̣nu bà ni ́ sọ ́ki ́ niń ú àpilẹ̀kọ yi ̀i.́

Kì í kúku ́ sẹ wi ́ pe ́ aẁ a Yorùba ́ kì í tàkurọ̀so ̣ niṕ a iṣẹ-́ ọnà at̀ i aẁ or̀ ań yi ý a ̀ ki ́ o ́ toó ́ di wí pé ́ aẁ oṇ eè ̀bo ́ de ́ si ́ ori ́lè ̣ ède ̀ wa. Am̀ ó ̣ lat́ i ig̀ ba ̀ ti ́ wó ̣n ti de,́ at̀ ip̀ a ́ at̀ i ̀kuú ̀ku ̀ ni eè ̀bo ́ fi ́ fé ̣ fi ède ̀ gba àkàtà ló ̣wó ̣ aki t́ i.̀ Bi ́ a ba ́ ti ibi is̀ ạ ń a ́ ki ý e ̀ sọ ó g̀ uǹ , a o ́ ri ́ i dáju ́ wí pé ́ ède ̀ eè ̀bo ́ o ̀ sẹ e ́ ronu ́ láis̀ ì ̣na,̀ tàbi ́ ja ́ si ́ kot̀ o,̀ tàbi ́ ká koḷu gegele, bi ́ a bá fé ̣ so ̣ ot̀ i t́ ọ́ or̀ ̣ ọ̀ lórí as̀ ạ ̀ at̀ i iṣẹ-́ ọnà àwọn Yoruba. Gé ̣gé ̣ bi ́ ohuǹ ti ́ Baba Awiś ẹ ̣Wań de ́ Abiḿ boĺ ̣a ́ kó ̣ wa niǵ ba ̀ reẁ ereẁ e, wó ̣n ni, “Ohun ti ́ o ́ ba ́ jo ̣ ara ni a ̀ a ́ fii ́ weŕ a; eè p̀ o ẹ̀pa ̀ o ́ jo ̣ poś i ́ el̀ ̣iŕ i.́”4 Eè ̀bo ́ siś o ̣ ni ́ gbeṛ ef̣ u ò sẹ é tú àdi ̀i t̀ ú ọ̀rọ̀ ti ́ a ta ni ́ kóko,́ ti ́ aẁ oṇ oḷó ̣nà di ̀ bi ́i isụ aǹ a siń u ́ isẹ́ ̣ oẉ ó ̣, isẹ́ ̣ oju,́ at̀ i isẹ́ ̣e ̣ laà ́kaỳ e,̀ ti ́ a n ́ pe ̀ ni ́ oṇ a ̀ ni ́ èdeè Yorùba.́ Ti ́ a o ̀ bá ni ́i ́ tan ara wa je,̣ kò si ́ bi ́ a sẹ lè so ̣ ọ̀rọ̀ kó pọ̀ to,́ kò ni ́i ́ kuń inú agbọǹ . Kò si ́ bi ́ a sẹ lè fi èdè eè ̀bó sẹ ap̀ èjuẃ e at̀ i ar̀ òfò ̣ ti ́ ó lè muń á dóko fuń aǹ -̀ faà ǹ i ́ i t̀ umọ̀ oṇ à aẁ oṇ Yorùba.

Bàbá Lam̀ i ́di ̀ Oḷoń àdé Fáké ̣yé ̣, ki ́ Olódum̀ arè ó deḷẹ̀ fuń woṇ , ni woń ̣

so ̣ or̀ ̣ ọ̀ i ̀jiǹ lẹ̀ kan niǵ bà ti ́ a ń dá woṇ ló ̣ lá pẹ̀ lú iẁ é kan ti ́ mo sẹ oloó t̀ ú rẹ̀ ni oḍ uń 1988.5 Bàbá Fáké ̣ye ̣ wo iẁ é yi ̀i ́ niǵ bà ti ́ mo gbé e fuń woṇ yeẁ ̣ o,̀ wó ̣n ré ̣ri ̀iń . Mo ni ́ kí ló de,́ baba? Baba ni, “Moỵ ọ̀, ọ̀rọ̀ at̀ at̀ a ̀ bi ́ is̀ ọ ḳ uś ọ .̣ Ẹ̀yin alákọ̀we,́ e ̣ roṛ a maá puró ̣ ojúkoroju.́” Mo ni,́ “Baba, ki ́ le ̣ ri ?́ ” Baba dáhuǹ , wó ̣n ni,́ “Eè t́ ijé ̣ Moỵ ọ̀! Gbà raǹ mi ́ ti ṣe wá deḷ é ̣ru.̀ Jé ̣ jé ̣ ni mo gbég̣ ii ̀ ni ́ op̀ oḿ úleŕ ó moj̣ a àlekaǹ . Ta ni ́ wa mọ̀ wí pé ́ eè ̀bó rep̣ eṭe ̣ baý i ̀i ́ ń bé ̣ niń ú igi ose!̀ Am̀ ó ̣ sa,́ gbé ̣nag̀ bé ̣na ̀ ti gbé ̣ igi tań o. O ́ ku ti gbeń ̣ ugbé ̣nu.” Mo dáhuǹ , mo ni,́ “Àki ́i ̀ka,̀ baba.” Baba Fáké ̣ye ̣ waá ́ sị ́ iẁ é oẉ ó ̣ woṇ , wó ̣n ni,́ “Ki ́ ni gbogbo eè ̀bó gbeṛ ef̣ u tó ̣ o ̣ waá ́ ko ̣ kalè ̣ yi ̀i ́ fi jo ̣ iṣẹ-́ ọnà ti ́ mo gbé ̣?” Mo ni,́ “Baba, o ́ kúku ́ joṛ a, lójuú tem̀ i o.” Baba ́ ré ̣ri ̀iń keè -́ keè .́ Baba ́ ni,́ “Ṣe ́ gbogbo eè ̀bo ̀ inu ́ iẁ e ́ yi ̀i ́ sẹ e ́ tuḿ ọ̀ si ́ ède ̀ Yoruba?” N o ̀ ronu ́ lé ̣ẹ̀meji ̀ ti ́ mo fi foḥ uǹ wi ́ pe,́ “Aẃ u,̀ sẹ bi ́ ki ́ wó ̣n kaǹ tuḿ ọ̀ rẹ̀ laś ań lat́ i èdè Oỳ iǹ bó si ́ Yorùbá ni.” Baba ni,́ “Moỵ ọ̀, kò ri ́ bé ̣è.̣ Èdè eè ̀bó kọ̀ jo ̣ Yoòbá o. Bi ́ eè ̀bó bá sẹ é poẁ e, sẹ ́ ó sẹ é pof̣ọ̀? Bi ́ eṇ a,̀ bi ́ og̀ ède,̀ bi ́ aỳ ájó ̣, bi ́ i er̀ em̀ ọ̀ jé ńko,̣ sẹ ́ e ̣ lè fi eè ̀bó ki ori ́ki ̀ i ̀di ́le?́ ” Mo dáhuǹ , mo ni,́ “O ́ kúku ́ sẹ e ́ sẹ , baba. Ni ́ Amé ̣ri ́ka,̀ wó ̣n ti ń fi Oỳ iǹ bó dáfa.́” Baba Fákéỵ e ̣ ni,́ “Bó bá ri ́ bé ̣e,̀ ̣ ki ́ ni “Ilẹ̀e ̣ kaá à ŕ ọ̀, o ò ji ́ire” ni ́ èdeè eè ̀bo?́ ”

Ig̀ bá yi ̀i ́ ni mo tó mò ̣ ibi ti ́ baba ń lo,̣ láim̀ o ̣ ibi ti ́ babá ti ń bò.̣

Bi ́ ède ̀ Yorùba ́ o ̀ ti le ̀ parada ̀ loó r̀ o ́ di ́ eè ̀bo,́ bé ̣ẹ̀ naá ̀ ni eè ̀bo ́ o ̀ lee ̀ parada ̀ di Yorùba.́ Bi ́ a bá ni ́ ká dań an wo,̀ a ò ni ́ ri ́ eeǵ uń mọ̀, mor̀ ̣ iẁ ò laś ań ni araǹ ojú ó maá je.̣ Èkiń i ́ ni wi ́ pé èdè at̀ i as̀ ạ ̀ Yorùba,́ Taý é at̀ i Ké ̣ hiǹ dé ni wó ̣n jé ̣. Bi ́ ọ̀̀kań bá ti yẹ̀ba,́ er̀ e i ̀beji ̀ ni ó ku,̀ èjìrẹ́ ará Is̀ ọ kuǹ ti relé ojú oḷó ̣mo ̣ ò tó o. Gé ̣gé ̣ bi ́ Baba Fáké ̣ye ̣ ti wi,́ eṇ i ́ bá ń fi èdè eè ̀bó tuḿ ọ̀ oṇ à Yorùba,́ ó ti ya Taý é kuŕ ò ló ̣ dọ̀ Oṃ ó ̣ ké ̣ hiǹ de.́ At̀ amó ̣ mó ̣ at̀ amọ̀ ni ó ku,̀ afì bi ́ Baba Fáké ̣ye ̣ bá jé ̣ ọ̀gbẹ̀ri ̀ niṕ a iṣẹ-́ ọnà aẁ oṇ Yorùba.́ Èkeji ̀ ni wi ́ pe,́ gbogbo èdè ni ó ni ́ i ̀di ́ àbájo ̣ ti ́ ó yat̀ ò ̣ si ́ ara a woṇ , ti ́ og̀ bẹ̀ri ̀ ò mo.̀ ̣ I ̀di ́ abájo ̣ ède ́ da ̀ bi ́ oò g̀ uǹ ti ́ oṃ oḍ e ́ ri ́ ti ́ o ́ wa ́ n ́ pe ̀ ni ́ ef̀ ̣ó ̣. Bi ́ a fi ewe ́ ède ̀ han àlejo,̀ a o ̀ gboḍ ọ̀ ja ́ a le ́ e ló ̣wó ̣; a si ̀ lee ̀ ja ́ a le ́ e ló ̣wó ̣, ki ́ a ́ mó ̣ so ̣ oó ̣ ko ̣ ti ́ n ́ jé ̣ fuń un. Adi ́fa ́ fuń ag̀ bè ̣ to ́ lóko, ti ́ o ̀ ló ̣ kó;̣ bi ́ oko ́ ba ́ kuń ńko,̣ kiń i ag̀ bẹ̀ yió ̀ fi ro o?́ Ni t́ ori ́i kiń i ?́ Ni t́ ori ́i lé ̣na,̀ lé ̣na,̀ là ń fo ̣ èdè Yorùba,́ gég̣ é ̣ bi ́ Baba Abió ́ ̣ duń ti wi ́ niń ú iẁ é yi ̀i.́ Baba Abió ́ ̣ duń ni ́ eṇ à lo paradà tó doṇ a;̀ oṇ à naá ̀ tuń wá pawó ̣ da,̀ ó deṇ a,̀ ó di or̀ ̣ ọ̀ huǹ -nu-̀ huǹ -nu.̀

Ki ́ ni eṇ à ti ́ ń be ̣ niń ú èdè Geè ̣́ ̣si ?̀ Ri ̀ki ś i ́ ni. Alaǵ bẹ̀de ̣ èdeè Gẹ̀é ̣si ̀ ò ri ́ bébà oṇ à Yorùba ro.̣ Bi ́ eǹ i ỳ aǹ bá ti ber̀ ̣ è ̣ si ́ ni ́i ́ so ̣ èdè Gẹ̀é ̣si,̀ oluẃ a rẹ̀ ti kó siń ú pańpé ̣. E ̣ jé ̣ ki ́ á ti ibi peḷeḅ e ̣ mú ọ̀ọ̀ lẹ̀ je,̣ ká ti ibi i s̀ ạ ń á ki ý è si ́ oò g̀ uǹ . Kiń i i t̀ umọ̀ “art” ni ́ ède ̀ Yorùba?́ I ̀beé r̀ e ̀ sákála ́ yi ̀i ́ ko ̀ keŕ eḿ i ́ raŕ a.́ Ni ́ àkó ̣ kó ̣, i ̀beé r̀ è yi ̀i ́ dàbi ́i ig̀ bà ti ́ eǹ i ỳ aǹ ń fi eṛ an jẹ̀ko.̣ A lè wí pé ́ “oṇ a”̀ ni i t̀ umọ̀ “art” ni ́ Yorùba.́ Am̀ ó ̣ ti ́ a bá fi laà ́kaỳ è wo i ̀beé r̀ è naá ,̀ a ó ri ́ i wi pé inú pam̄pé ̣ ni i ̀beé r̀ è yi ̀ i ́ ti ni si.́ Ki ̀ i ́ sẹ i ̀beé r̀ è ti ́ ó waý é raŕ a,́ ni t́ ori ́ i ̀beé r̀ è ẹ̀de ̣ ni. I ̀dáhuǹ ti ́ ó ye ̣ i ̀beé r̀ è ed̀ ̣ e ̣ beé ̣̣̀ ni ỳ i ́i :́ ki ́ ni i ̀di ́ ti ́ aẁ oṇ Yorùbá fi ni ́ lat́ i ni ́ i t̀ umọ̀ fuń “art?” Ǹjé ̣ eṇ iké ̣ni ti bi aẁ oṇ Geẹ ś ̣ i ̀ ri ́ wi ́ pé ki ́ ni i t̀ umọ̀ “Ig̀ unnu” ni ́ èdè Oỳ iǹ bo?́ Bi ́ a bá ti bi ni wi ́ pé ki ́ ni i t̀ um̀ ọ̀ “art” ni ́ èdè Yorùba,́ ó di wí pé ́ ki ́ á wá maá fi oẉ ó ̣ hoṛ i,́ ki ́ á má a wòke,̀ ki ́ á má a làkàka,̀ ni t́ ori ́ pé ó dàbi ́ ig̀ bà ti ́ ó di dandan ki ́ aẁ oṇ Yorùbá ni ́ i t̀ umò ̣ fun “art” ni ́ èdè abiń ibi ́i woṇ . Am̀ ó ̣, tani ó sẹ ofì n yi ̀i ́ wí pé ́ gbogbo as̀ ạ ̀kasạ ̀ ti ́ aẁ oṇ Geè ̣ ś ̣ i ̀ bá ti dá ni ́ im̀ ọ̀raǹ , aẁ oṇ Yorùbá ni ́ lat́ i ni ́ i t̀ umọ̀ fuń , niẃ ọ̀n ig̀ bà ti ́ ó jé ̣ wí pé ́ eṇ i ̀kan ki ̀ i ́ ka irú eḅ o ̣ bé ̣ ẹ̀ fuń aẁ oṇ eè ̀bo?̀

Ohun ti ́ ó fa irúfé ̣ i r̀ oǹ ú eleý i ̀i ́ ni wí pé ́ aẁ oṇ eè ̀bò koḷoṇ ái s̀ i ̀ aẁ oṇ Yorùba.́ Mo moò ̣́ ̣mọ̀ lo “koḷoṇ áis̀ i ”̀ ni.6 Kiń i ́ n ́ jé ̣ “koḷoṇ áis̀ i ”̀ ni ́ ed̀ e ̀ Yorùba?́ Iró ̣ funfun ni o ́ wa ̀ ni ́ i ̀di ́ ọ̀rọ̀ naá .̀ Kóko ́ inu ́ ọ̀rọ̀ ti ́ a ̀ n ́ pe ̀ ni ́ “koḷoṇ áis̀ i ”̀ ni “kó ̣ ló ̣ni.̀” Aẁ oṇ eè ̀bo ́ wa ́ si ́ oko bàbá mi, wó ̣n so ̣ ó ̣ di “kó ̣ ló ̣ni ̀i” woṇ . O ́ dàbi ́ ig̀ bà ti ́ mo bá wo eẁ ̣ ù ti ́ e ̣ wọ̀ soŕ ̣ uǹ baý i ̌, ti ́ mo wí pé ́ “Ewuu Moỵ ọ̀ ni ỳ i ̌.” Nś ẹ ni e ̣ ó wò mi ́ ti ỳ anu-ti ỳ anu, ti ́ e ̣ ó so ̣ wí pé,́ “Àbi ́ o ti mu sẹ̣̀kẹ̀té ̣ yó ni Moỵ ọ̀sọ́ ̣re?̣ ” Sụ g̀ boń ni t́ ori ́ wi ́ pé èdeè Gẹ̀é ̣si ̀ ni eè ̀bó lo,̀ ti ́ wó ̣n pe ilé baba wa ni ́ “koĺ ̣ó ̣ni,̀ ” ọ̀rọ̀ naá ̀ ò yé wa wí pé ́ ilé baba wa ki ̀ i ́ sẹ koĺ ̣ó ̣ni ̀ baba ńlá woṇ . Am̀ ó ̣ tori ́ wi ́ pe ́ giŕ aḿ ọ̀ Geè ̣́ ̣si ̀ ni wó ̣n n ́ so,̣ kọ̀ pé ̣ ko ̀ jiǹ na,̀ ti ́ wó ̣n fi di “koḷoṇ áiś a”̀ ti ́ ń sẹ “koḷoṇ aiś eś aǹ ,” ti ́ aẁ a eṛ ú Oḷó ̣run naá ̀ si ̀ di er̀ ò ti ́ wó ̣n “koḷoṇ áis̀ i.̀” Aẁ oṇ akoẁ ̣ eé wa si ̀ ti ber̀ ̣ ẹ̀ si ́ ni ́i ́ ko ̣ iẁ é loŕ i ́i “positi-kòloń i á ́ sitoḍ i.̀”7 Or̀ ̣ ọ̀ naá ̀ wá di i t̀ aǹ ài t̀ et̀ em̀ óle,̀ olè ń sá lo!̣ Lat́ i i ̀bẹ̀rẹ̀ ni ó ye ̣ ki ́ á ti ́ so ̣ fuń eè ̀bó wi ́ pe,́ “Alag̀ ba,̀ sẹ ́ kì í sẹ wí pé ́ e ̣ mu sig̀ aá kùkuý e?̀ Ilé baba tem̀ i ki ̀ i ́ sẹ ‘kó ̣ ló ̣ni ’̀ re ̣ oò .” Gbogbo em̀ i ni “positi-kòloń iá ́ sitoḍ i ”̀ o ̀ tilẹ̀ ni ́i ́ waý e,́ tàbi ́ ki ́ o ́ ni ́ i t̀ umọ̀ kankan. Ède ̀ oỳ iǹ bo ́ ni o ́ da ́ “koĺ ̣ó ̣ni ”̀ si ́lè ̣ ni ́bi ti ́ ko ̀ si ́ ǹkan ti ́ o ́ n ́ jé ̣ bé ̣è.̣ Où n naá ̀ ni o ́ si ̀ fa wi ́ pe ́ a wa ́ a ́ bẹ̀rẹ̀ si ́ i ́ sẹ “positikòloń iá ́ sitoḍ i” ̀ lój̣ ó ̣ oǹ i.́ Iró ̣ ni ́ n ́ jé ̣ beẹ́ ̣ .̀ Sụ g̀ bó ̣n iró ̣ yi ̀i ́ yóò jo ̣ oò t́ o ́ bi ́ a ba ́ ń fi èdè Oỳ iǹ bó ronu.́ I ̀di ́ rè é ti ́ oṃ o ̣ Yorùbá kò gboḍ ọ̀ maá fi èdè eè ́bó ronu,́ ti ́ ò bá fé ̣ kó si ́ kot̀ o.̀ Ar̀ osó ̣ dọ̀ ni oḳ ó ̣ èdè Oỳ iǹ bó ń roko.

Oniŕ uú ruú ri ̀kiś i ́ at̀ i ar̀ osó ̣ dọ̀ ni eè ́bo ́ ti fi oḳ ó ̣ ède ̀ woṇ ro ni ́ ilẹ̀ Afirika. Wó ̣n kó ̣ kó ̣ wo ̀ iṣẹ-́ ọnà Afí ŕ i ́ka ̀ suǹ -uǹ , wó ̣n bẹ̀rẹ̀ peḷu “pir̀ im̀ i t́ i ́fu ́ art.” Wó ̣n kọ̀wé lo ̣ jań t̀ i ̀ reṛ e ̣ loŕ i ́i “pi r̀ im̀ i ́ti ́fú art.” Paul S. Wingert (ni ́ 1962)8 ati Douglas Newton (ni ́ 1978)9 ko ̣ iẁ é bam̀ ̀ba-̀ bamba lat́ i wi ́ pé “pi r̀ im̀ i t́ i ́fú art” ni aẁ a eǹ i ỳ aǹ -an Afí ŕ i ́kà ń sẹ ; láip̀ é ̣ woń ni ́ ìwà i ̀kà ni aẁ ó ̣n ń hù bi ́ aẁ oń ̣ bá ń pe isẹ́ ̣ Afí ŕ i ́kà ni “pi r̀ im̀ i t́ i ́fú art,” at̀ i wi ́ pé “ti ŕ ái ́báli ́ art” ni aẁ oṇ yió ̀ má a pè e.́ Láip̀ é ̣ yi ̀i ́ ni Jean-Baptiste Bacquart sẹ iẁ é alaŕ àbarà loŕ i ́i piṕ e iṣẹ-́ ọnàa Afí ŕ i ́kà ni ́ “ti ŕ ái ́báli ́ art,” ti ́ ó fi ok̀ ̣ é ̣ àim̀ ọye aẁ or̀ ań sẹ loś ̣ ọ ̣̀ó ̣.10 Am̀ ó ̣ kè è sú woṇ o! Wó ̣n tuń wò lo ̣ sàkuǹ , wó ̣n ni ́ aẁ oṇ ó ber̀ ̣ ẹ̀ si ́ maá pe isẹ́ ̣ Afí ŕ i ́kà ni “tiradi ś ạ ń ná art.” Alag̀ bà John Picton, ni ́ oḍ uń -un 1992,11 sẹ òp̣ ọ̀ lop̣ ọ̀ àlaỳ é wi ́ pé kò bójú mu lat́ i pe iṣẹ-́ ọnà Afí ŕ i ́kà ni ́ tiradi ś ạ ń ná art. Am̀ ó ̣ bi ́ araý é bá gbó,̣ woṇ ò gba.̀ Woṇ ò yeé ́ pe isẹ́ ̣ Afí ŕ i ́kà ni ́ tiradi ś ạ ń ná art. Eè ̀bó mi ̀i ŕ aǹ a pè isẹ́ ̣ Afí ŕ i ́kà ni ́ i s̀ i t̀ oŕ i ́ká art. Tàbi ́ ki ́laś i ́ká art. Ọr̀ ọ̀ ̣ oóko ̣ ti ́ wó ̣n ó maá pe isẹ́ ̣ Afí ŕ i ́kà ti waá ́ dar̀ ú bi ́ eṣ ẹ̀e ̣ télọ̀. Kò tilè ̣ yé aẁ oṇ eè ̀bó mó;̣ bi ́ ó sẹ wu koẃ ȧ ni kálukú ti ń sẹ . Asọ ̣ ò bá oṃ ó ̣ye ̣ woṇ mó ̣. Ó ti rin i ̀hòhò woj̣ a.̀

Ohun tó sẹ ni ni ́ kaỳ efí ̀ ni wi ́ pé aẁ oṇ ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Afí ŕ i ́kà naa ti wá ń fi oḳ ó ̣ èdè geè ̣́ ̣si ̀ roko si ́ ọ̀dọ̀ aẁ oṇ Oỳ iǹ bo;́ wó ̣n so ̣ oḳ ó ̣o tiwoṇ si ǵ bo,́ won ò lè dá inú rò mo.́ ̣ Bi ́ eè ̀bó bá ti wi ́ naá ̀ ni ó té ̣ wọn ló ̣ruǹ . Bi ́ eè ̀bó bá ni ́ “Jókòó,” woṇ a jókòó; “di ̀de,” woṇ á di ̀de, “loś òó,” woṇ á loś òó. Sẹ bi ́ èdè eè ̀bó ni wó ̣n ń so;̣ as̀ ạ ̀ eè ̀bó ni woń ̣ ń da.́ Eléduà ̀ má so ̣ wá di ajá eè ̀bo.́ Kò pé ̣ kò jiǹ na,̀ eè ̀bó tuń wi ́ pé abala kan ni ń ú aẁ oṇ ayaẁ or̀ ań ilẹ̀e ̣ Afí ŕ i ́kà yat̀ ọ̀ pat́ aṕ at́ á si ́ aẁ oṇ ti ́ aẁ ó ̣n so ̣ ni “tiradiś ạ ń na,̀” ni t́ ori ́ pé aẁ oń ̣abala ti ́ aẁ ó ̣n ya ̀ só ̣tọ̀ yi ̀i ́ lo ̣ si ́ ile ́ ẹ̀kó ̣ i ỳ aẁ or̀ ań . Sẹ ́ ogunlóg̣ oọ ̣ eè ̀bo ́ o ̀ kúku ́ gbà pé aẁ oṇ ti ́ wó ̣n kà kuń tiradi ś ạ ń ná lo ̣ si ́ ilé ẹ̀ kó ̣ i ỳ aẁ or̀ ań . Eè ̀bó bá bẹ̀rè ̣ si ́ i ́ tuń pe abala yi ̀i ́ ni ́ kọ̀nt̀ é ̣mṕ oŕ aŕ i.̀ Bi ́ ó bá wù wó ̣n, woṇ a tuń pe abala yi ̀i ́ ni ́ mó ̣ daá ǹ i ̀ (modern). Woṇ a fo ̣ eè ̀bo ti t́ i ́ bi ́ ọ̀peé ̣̣̀rẹ̀, lái ̀ mú iná dóko.

Ki ̀ i ́ kúku ́ sẹ wi ́ pe ́ iẁ a ̀ i ̀ka ̀ ni ̀kan ni i ̀di ́ abájo ̣ ti ́ ọ̀pọ̀ lop̣ o ̀ aẁ oṇ Eè ̀bo ́ fi ń dá àbá a gbar̀ anm̀ i ́ deḷeŕ ̣ u.̀ Ogunlóg̣ ò ̣ ig̀ ba,̀ bi ́ aà ý á bá ni ́ ki ́ où ń tuń ojú oṃ o ̣ sẹ , i ̀ka ni ́i ́ ti ̀ bọ̀ ó ̣, ti ́ ojú yóò wá di yi ý ẹ̀. Ó mú mi ni ŕ an ikú ọ̀mọ̀wé John Pemberton III, eṇ i ti ́ ó sạ láis̀ i ́ láip̀ e.́ ̣ Mo sẹ alábàápàdé woṇ ni ́ Ilé Ifè ̣ ni 1984, ni ́ ibi ti ́ wó ̣n ti ń fi gbogbo ara sẹ isẹ́ ̣ iẁ ádìí pẹ̀ lú Bàbá Fákẹý ẹ. Bi Pemberton ti ́ ń nar̀ ó ni wó ̣n ń kuŕ ú lat́ i ya fó ̣tò per̀ ̣ e-̀ ̣ pẹ̀rẹ̀, ti ́ wó ̣n ń fi pé ̣ẹ̀ni ̀ haǹ t̀ uŕ ú or̀ ̣ ọ̀ soŕ i ́ ewe,́ ti ́ wó ̣n ń beè r̀ è àlaỳ e,́ ti ́ woń ̣ ń fi asọ ̣ nuju,́ ti ́ oò ǵ uǹ si ̀ bo ̀ woń ̣ , bi ́ wó ̣n sẹ n ́ só ̣ Baba Fákéỵ e,̣ eṇ i ti ́ n ́ feṛ an jẹ̀ko ̣ gbé ̣ Oseé Sạ ǹ go.́

Jel̀ ̣é ̣ńké ̣ ni Baba Fákéỵ e ̣ jókòó, ti ́ wó ̣n n ́ ré ̣ri ̌n muś ẹ́ ̣ leń ̣ u isẹ ́,̣ lái ̀ tilè ̣ woju ́ Pemberton ti ́ ó ti ilẹ̀ Amerika wá á sẹ isẹ́ ̣ iẁ adìí ni ́ Ilé Ifè.̣ Am̀ ó ̣ sạ ́ niǵ bà ti ́ mo ka ar̀ òko ̣ ti ́ Pemberton ko ̣ siń ú iẁ é àkójop̣ ọ̀ aẁ or̀ ań kan ti ́ orúkọ̀ rẹ̀ ń jé ̣ Art and Oracle: African Art and Rituals of Divination, og̀ ẹ̀dẹ̀ dúdú ni, kò yá bù sań .12 Alákọọ̀ ́kó ̣, emi ni i t̀ umọ̀ oóko ̣ iẁ é yi ̌ ni ́ Yorùba?́ Ki ́ ni ́ ń jé ̣ oracle, rituals at̀ i divination ni ́ ojúloẃ ó Yorùba? Lái s̀ i ́ aǹ i-́ aǹ i,́ Ọ̀mọ̀wé Alisa LaGamma, oloó t̀ ú àkójop̣ ò ̣ aẁ or̀ ań wọ̀nyi ́ lat́ i ilẹ̀ eè ỳ aǹ dúdú ń fi Gẹ̀é ̣si ̀ ronú ni niǵ bà ti ́ ó sạ aẁ oṇ er̀ e inú iẁ é yìí jo.̣ Oḳ ó ̣o ̣ Geè ̣́ ̣si ̀ ni wó ̣n fi ro gbogbo oko ti ́ ń be ̣ niń ú iwe àkójopọ̀ yi ̌. Lat́ i i ̀bẹ̀rẹ̀ ti t́ i ́ dé op̀ in, iẁ é yìí ko ̀ yo ̣ obi ̀ laṕ o,̀ bé ̣ẹ̀ ni ko ̀ wu ́ ni loŕ i ́ ti ́ a ba ́ n ́ fi suǹ -nu-̀ kuǹ ojuú Yorùba ́ wo ̀ o.́ Artifact, aesthetic qualities, ancestral spiritual realm, figurative at̀ i gbogbo kóko ́ ọ̀rọ̀ ti ́ m ́ be ̣ ni ́ oju ́ ewe ́ ki ̌nni ́ ni ̀kan ti to ́ lat́ i mu ́ inu ́ run oṃ o ̣ Yoòba ́ ti ́ n ́ fi ède ̀ abiń ibi ́ ronu.́ Kiń i làbaŕ i ̀i “Dynamic Devices: Kinetic Oracles?” Ko ̀ loŕ i,́ ko ̀ ni ́di ̌. Iconography, pluralistic vision, visual metaphor, human protagonists, abstraction, realism, at̀ i aẁ oṇ i ̀kòkò ọ̀rọ̀ yòókù ti ́ ń be ̣ niń ú iẁ e yìí kò se isụ jinna ni ́ èdè Yorùba.́

Gbogbo pálapàla yi ̀i ́ ni Ọ̀ jọ̀gbó ̣n Rowland Abió ́ ̣ duń ri,́ ti ́ wó ̣n fi wi ́ pe,́ họ̀ó ̣wu:̀ bi ́ a kò bá mo ̣ ibi a ń lo,̣ ó sạ á ̀ ni ́ ibi ti ́ a ti ḿbọ̀! Ọ̀ jọ̀gbó ̣n Abió ḍ u̇n ni,́ bi ́ a ba ́ n ́ sunkuń a ̀ ma ́ a riŕ an. Sẹ bi ́ aẁ a Yorùba ́ ni ́ ède ̀ wa ti ́ a fi n ́ tuḿ ọ̀ aẁ oṇ iṣẹ-́ ọnàa wa? Sẹ bi ́ aẁ oṇ ọ̀mọ̀wé bi ́i Ọ̀ jọ̀gbó ̣n Ag̀ bà Oḷaś op̣ é Oyě laŕ aǹ ti kó ̣ wa lat́ i ko ̣ èdè Yorùbá si ́lè ̣ pel̀ ̣ú ir̀ or̀ ̣ uǹ ?13 Àbi ́ eè ̀di ̀ fé ̣ mú alaś o ̣ kan ni? Sẹ bi ́ Yorùbá ni ́ oẁ e, àdi ̀i t̀ ú ède,̀ orin, àló,̣ i t̀ aǹ , i ỳ er̀ ̣ e,̀ ̣ er̀ em̀ ọ̀ je,́ aỳ ájó,̣ og̀ ède,̀ at̀ i ori ś iri ś i eẉ à èdè ti ́ ó jé ̣ atuḿ ò ̣ fuń aẁ oṇ iṣẹ-́ ọnà woǹ ̣ yi ?́ Ki ́ ló wá fa réderède bi ́i “pir̀ im̀ i t́ i ́fu,́ ti ŕ ái ́báli,́ tiradi ś ạ ń na,̀ i s̀ i t̀ oŕ i ́ka,́ ki ́laś i ́ka,́ kọ̀nt̀ é ̣mṕ oŕ aŕ i,̀ mó ̣ daá ǹ i ”̀ at̀ i gbogbo jat́ ijat̀ i baú n? Eè ś e ti ́ aẁ oṇ eè ̀bo ́ ti ́ wó ̣n mo ̣ i ỳ á Ọ̀sọ́ ̣ ju Ọ̀sọ ́ wá ń dá orin, ti ́ aẁ a om̀ ̣ ọ̀weé Yorùbá ná à si ̀ ḿ bá woṇ gbe ̀ e,́ bi ́ eṇ i ti ́ ko ̀ mo ̣ oju,́ ti ́ ko ̀ mo ̣ ara? Ọ̀ jọ̀gbó ̣n Abió ḍ uń ni,́ i ̀ka ti ́ o ́ ba ́ tó ̣ si ́ imu ́ la a n ́ fi ro imu.́ A ki ̀ i ́ tori ́i gbiǵ bo ́ paja.́ A kì í tori ́i ki ́kaǹ pa ag̀ bo.̀ Eṇ i ̀ kan ki ̀i tori ́i weŕ ewer̀ e pa òbúko.̣ Élé ̣nu riŕ i ̀ ni ó ni aà m̀ ù i ỳ aá re.̀ ̣ Ède,̀ as̀ ạ ̀ at̀ i iẁ a ̀ Yorùba ́ ni o ́ bi ́ isẹ ́ ̣ oṇ a ̀ Yorùba.́ Eṇ i ́ ba ́ bi ́ ni la ̀ a ́ jo.̣ Ọ̀ jọ̀gbó ̣n Abió ḍ uń ni, ó tó gé ̣e.́ ̣ Alubat̀ á ki ̀ i ́ daŕ in. Eṇ i ̀ kan ò gboḍ ọ̀ gbé oṃ o ̣ Oḅ à fuń Ọ̀sụ n. Dié ̣̀ ninu aẁ oṇ i ̀di ́ abájo ̣ ni ỳ i ́i ti ́ Ọ̀ jọ̀gbó ̣n Abió ḍ uń fi ko ̣ iẁ é ti ́ gbogbo ag̀ baý é ń kà ti ́ wó ̣n ń miri,́ ti ́ a si ̀ péjo ̣ jókòó lat́ i ye ̣ wò ni ́ oj̣ ó ̣ oǹ i.́ Baba Abió ́ ̣ duń ki ̀ i ́ foḥ uǹ , wó ̣n ti i ̀ka bọ̀ woń ̣ lé ̣nu ni. Ọ̀rò ̣ ló kó mo kó mo rò de.́

Awọn Ìwé Ìtọkasí

Abimbola, Wande. 1975. Ed., Yoruba Oral Tradition (Ile-Ife: Department of African Languages and Literatures, University of Ife.
Abiodun, Rowland. 2014. Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art. New York: Cambridge University Press.
Bacquart, Bacquart. The Tribal Arts of Africa: Surveying Africa’s Artistic Geography. London: Thames and Hudson, 2002.
Bamgbose, Ayo. Yoruba Orthography: A Linguistic Appraisal With Suggestions for Reform. Ibadan: Ibadan University Press, 1965.
Bascom, William R. 1973. African Art in Cultural Perspective. New York: Norton.
Cornet, Joseph. 1971. Art of Africa, Treasures from the Congo, translated by Barbara Thompson. London: Phaidon.
Blier, Suzanne Preston. 2015. Art and Risk in Ancient Yoruba: Ife History, Power, and Identity c. 1300. New York: Cambridge University Press.
Drewal, Henry, and Pemberton, John, with Abiodun, Rowland. 1989. Yoruba: Nine Centuries of African Art and Thoughts. New York: Center ofAfrican Art and Harry N. Abrams.
Fagg, William, and John Pemberton. 1982. Yoruba Sculpture of West Africa, edited by Bryce Holcombe. New York: Knopf.
Joint Consultative Committee on Education. 1974. Revised Official Orthography for the Yoruba Language: Yoruba orthography. Lagos: The Committee. LaGamma, Alisa, and Pemberton, John. 2000. Art and Oracle: African Art and Rituals of Divination. New York, N.Y. Metropolitan Museum of Art Metropolitan.
Nardo, Don. 2010. The European Colonization of Africa. New York: Morgan Reynold, 2010.
Newton, Douglas. 1978. Masterpieces of primitive Art. New York: Knopf.
Okediji, Oladejo. 1969. Àjà Ló Leṛ u.̀ Ibadan: Longman Nigeria Limited.
Olajubu, Oludare. 1972. Àkó j̣ op̣ ọ̀ Iwi ̀ Eguń guń . Ibadan. Longman Nigeria Limited.
Picton, John. 1992. “On the Invention of ‘Traditional’ Art,” in Moyo Okediji, ed., Principles of `Traditional’ African Culture. Ibadan: Bard Book.
Oyelaran, Olasope. 1977. “Linguistic Speculations on Yoruba History.” Seminar Series, vol. I, Part II. Ile-Ife: Department of African Languages and Literatures, University of Ife: 624- 51.
Wingert, Paul S. 1962. Primitive Art: Its Traditions and Styles. New York: Oxford University Press.
Young, Crawford. 2012. The Postcolonial State in Africa: Fifty Years of Independence, 1960– 2010. Madison: University of Wisconsin Press.

Footnotes

1 Mo duṕ é ló ̣wó ̣ Michael Afolayan, eṇ i ti ́ ó tuḿ ọ̀ “sọ ́ki ”́ yi ̀ i ́ si ́ èdeè Gẹ̀é ̣si.̀
2 Mo fi ar̀ òko ̣ yi ̀i ́ júba ̀ fuń Oḷádẹ̀ jo ̣ Òkédi ̀ji,́ oǹ ̀kọ̀we ́ i t̀ aǹ ar̀ òko,̣ ere ́ ori ́ i t̀ ag̀ e,́ at̀ i ewi ̀ ni ́ ède ̀ Yorùba,́ eṇ i ti ́ o ́ kó ̣ mi lat́ i ko ̣ ède ̀ Yorùba ́ si ́le.́ ̣ Woń ̣ ki ̀ mi ́ ni ́ i ̀lọ̀ wi ́ pe ́ n ko ̀ gboḍ ọ̀ fi èdè Yorùbá ṣe aẁ àda,̀ ni t́ ori ́ wi ́ pé èdè abiń ibi ́ eṇ i sẹ pat̀ àki ̀ puṕ ò;̣ at̀ i wi ́ pé odò ti ́ ó bá ti sạ ǹ kuŕ ò ni ́ ori ŕ un rẹ̀, gbi ǵ be ̣ ni ́ i ́ gbe.̣ Wó ̣n kó ̣ mi ni ́ oẁ e, i t̀ aǹ at̀ i orin aẁ oṇ Yorubà lat́ i i g̀ bà ti ́ mo ti wà ni ́ jòjòlo.̀ At̀ aǹ dá Og̀ uń , mo ri ́bà o.
3 See Rowland Abiodun, Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art, (New York: Cambridge University Press, 2014).
4 Èkeji ̀ or̀ i s̀ ạ ̀ ni Awi ś ẹ ̣ Ag̀ baý e ́Wań de ́ Abiḿ bó ̣ la ́ jé ̣ niń u ́ ẹ̀kó ̣ ède ̀ Yorùba.́ N ko ̀ le ̀ gbag̀ bé láéláé ni ́ oj̣ ó ̣ kan niń ú ki ́laá s̀ i ̀ ti Yunifaś iti ̀ Ilé Ifè,̣ ni ́ oḍ uń 1973, ti ́ Awi ś ẹ ̣ ń kó ̣ wa ni ́ Ifa,́ ti ́ baba ́ so ̣ wi ́ pe,́ “Geé ś u ̀ Kirisi,̀ àbi ́ e ̣ ti n ́ pe ̀ e…́ .” Oṃ o ̣ oḍ uń mé ̣tàdiń loǵ uń ni mo jé ̣ ni ǵ bà naá .̀ Ẹ̀rù bà mi ́ ni ǵ bà ti ́ Awi ś ẹ̣ foḥ uǹ yi ̀i.́ N kò gbó ̣ iruẃ á ọ̀rọ̀ baý i ̀i ́ ri,́ gé ̣gé ̣ bi ́ eṇ i ti ́ wó ̣n ti fi ẹ̀sin aẁ oṇ Eè ̀bo ́ pa ni ́ iye ̀ lati piń ni ś iń . Sẹ ni mo ro ̀ wiṕ e ́ ar̀ a ́ yió ̀ sań lójiji ̀ lat́ i pa gbogbo aẁ a ti ́ a wà niń ú ki ́laá s̀ i ̀ naá .̀ Baba Abiḿ boĺ ̣á kaǹ ń dá obi ̀ je ̣ ni, bi ́ wó ̣n sẹ ń ki ̀ wá laý a,̀ ti ́ wó ̣n si ̀ ń kó ̣ wa ni ́ as̀ ạ ,̀ or̀ i s̀ ạ ,̀ at̀ i i ̀laǹ à aẁ oṇ Yorùba.́ Mo ri ́ba,́ mo ri ́bà o, Awi ś ẹ ̣ Ag̀ baý e,́ oṃ o ̣ baba Afàda-́ oẉ ó ̣-e-̣ pàjakum̀ ọ̀.
5 Moyo Okediji, ed., Yoruba Images; Essays in Honour of Lamidi Fakeye, (Ile Ife: Ife Humanities Society, Obafemi Awolowo University, 1988).
6 Don Nardo, The European Colonization of Africa, (New York: Morgan Reynold, 2010).
7 Crawford Young, The Postcolonial State in Africa: Fifty Years of Independence, 1960– 2010, (Madison: University of Wisconsin Press, 2012).
8 Paul S. Wingert, Primitive Art: Its Traditions and Styles, (New York: Oxford University Press, 1962).
9 Douglas Newton, Masterpieces of primitive Art, (New York: Knopf, 1978).
10 Bacquart, Jean-Baptiste. 2002. The Tribal Arts of Africa: Surveying Africa’s Artistic Geography. London: Thames and Hudson.
11 John Picton, “On the Invention of ‘Traditional’ Art,” in Moyo Okediji, ed., Principles of `Traditional’ African Culture, (Ibadan: Bard Book, 1992).
12 Alisa LaGamma, and John Pemberton, Art and Oracle: African Art and Rituals of Divination, (New York: N.Y. Metropolitan Museum of Art Metropolitan, 2000.
13 Ayo Bamgbose, Yoruba Orthography: A Linguistic Appraisal With Suggestions for Reform, (Ibadan: Ibadan University Press, 1965); Joint Consultative Committee on Education, Revised Official Orthography for the Yoruba Language: Yoruba orthography, (Lagos: The Committee, 1974). Òj̣ ọ̀gbó ̣n Oḷ aś op̣ é Oyě laŕ aǹ ni wóṇ kó ̣ mi ni ́ i ̀koṣ i ́lè ̣ èdeè Yorùbá ni ́ Yunifaś i t́ i ̀ Ile Ife lati 1973 titi di 1977; mo ri ́bà o.